Lára ààbọ̀ ti Ísírẹ́lì, yan ọ̀kan kúrò nínú àádọ́ta, (50) yálà ènìyàn, ẹran ọ̀sìn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹ̀yà ẹranko mìíràn. Kó wọn fún àwọn Léfì, tí ó dúró fún olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.”