Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 30:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ́ kí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè kí ìdè tí opó tàbí obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ bá ṣe yóò wà lórí rẹ̀.

10. “Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tabí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra,

11. tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró.

12. Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá sọ wọ́n dasán, nígbà tí ó gbọ́, nígbà náà kò sí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde tí yóò dúró, ọkọ rẹ̀ ti sọ wọ́n dasán, Olúwa yóò tu sílẹ̀.

13. Ọkọ rẹ̀ lè ṣe ìwádìí tàbí sọ ọ́ dasán ẹ̀jẹ́ tàbí ìbúrà ìdè tí ó ti ṣe láti fi de ara rẹ̀.

14. Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ kò bá sọ nǹkan kan sí í nípa rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́, nígbà náà ni ó se ìwádí nípa ẹ̀jẹ́ àti ìbúra ìdè tí ó dè é. Kí ọkùnrin náà se ìwádìí lórí rẹ̀ láì sọ nípa rẹ̀ si nígbà tí ó gbọ́ nípa rẹ̀.

15. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọkùnrin náà bá sọ ọ́ dasán, ní àkókò kan lẹ́yín tí ó ti gbọ́ wọn, nígbà náà ó jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.”

16. Èyí ni ìlànà tí Olúwa fún Mósè nípa ìbátan láàrin ọkùnrin àti obìnrin àti láàrin baba àti ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀ tí ó sì ń gbé ní ilé rẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 30