Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 29:14-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù mẹ́tàlá, pèsè ìyẹ̀fun òṣùwọ̀n ìdámẹ́wàá mẹ́ta tí a fi òróró pò pẹ̀lú ọ̀kọ̀kan, fún àgbò kan, bẹ́ẹ̀ ni fún àgbò méjèèjì,

15. àti fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́ àgùntàn kan. Bẹ́ẹ̀ ni fún ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rẹ̀ẹ̀rìnlá.

16. Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ọrẹ sísun gbogbo ìgbà ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu rẹ̀.

17. “ ‘Àti ní ijọ́ kejì ni kí ẹ̀yin kí ó fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù méjìlá, àgbò méjì àti ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá ọlọ́dún kan aláìlábùkù rúbọ.

18. Pẹ̀lú fún akọ màlúù, fún àgbò, àti fún ọ̀dọ́ àgùntàn kí ẹ pe ẹbọ ohun jíjẹ, àti ẹbọ ohun mímu, kí ó jẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà.

19. Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ mímu.

20. “ ‘Ní ọjọ́ kẹta, pèsè akọ màlúù mọ́kànlá, àgbò méjì, akọ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọdún kan tí kò ní àbùkù.

21. Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti akọ àgùntàn, pèsè ọrẹ ohun jíjẹ àti ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

22. Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹbọ sísun ìgbàgbogbo pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu

23. “ ‘Ní ọjọ́ kẹrin, pèsè akọ màlúù mẹ́wàá, àgbò méjì, àti ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 29