Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 28:24-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Báyìí ní kí ẹ ṣe se oúnjẹ fún ẹbọ tí a fi iná ṣe ní ojojúmọ́ fún ọjọ́ méje gẹ́gẹ́ bí olóòrùn dídùn sí Olúwa; ó gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí a fi iná ṣe ní àfikún ẹbọ ohun jíjẹ àti ohun mímu.

25. Ní ọjọ́ kéje kí ẹ̀yin kí ó ní ìpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe isẹ́ kankan.

26. “ ‘Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún Olúwa lẹ́yìn àsìkò Àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ se iṣẹ́ kankan.

27. Kí ẹ mú ẹbọ sísun ẹgbọrọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kan gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn fún Olúwa.

28. Pẹ́lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù ní kí ẹ rú ẹbọ ohun mímu ìdámẹ́ta pẹ̀lú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò pẹ̀lú àgbò kan.

29. Àti pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́ àgùntàn méje, kí ó jẹ́ ìdá kan nínú mẹ́wàá.

30. Ẹ fi òbukọ kan ṣe ètùtù fún ara yín.

31. Ẹ ṣe eléyí papọ̀ ní àfikún ẹbọ ohun mímu yín àti ẹbọ ohun jíjẹ yín. Kí ẹ sì ri dájú pé àwọn ẹranko náà jẹ́ aláìlábùkù.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 28