Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 26:33-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. (Selofehádì ọmọ Héférì kò sì ni ọmọkùnrin, bí kò ṣe ọmọbìnrin; orúkọ àwọn ọmọbìnrin Selofehádì ni Málà, Nóà, àti Hógílà, Mílíkà àti Táṣà).

34. Wọ̀nyí ni ìdílé Mánásè tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàámẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (52,700).

35. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Éfúráímù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:láti ọ̀dọ̀ Ṣútẹ́là, ìdílé àwọn ọmọ Ṣútẹ́là;ti Békérì, ìdílé àwọn ọmọ Békérì;ti Táhánì, ìdílé àwọn ọmọ Táhánì.

36. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣútélà:ti Éránì, ìdílé àwọn ọmo Éránì;

37. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Éfurémù, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàámẹ́rìndínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500).Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

38. Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nì yí:tí Bẹ́là, ìdílé àwọn ọmọ Bẹ́là;ti Ásíbérì, ìdílé àwọn ọmọ Ásíbérì;ti Áhírámù, ìdílé àwọn ọmọ Áhírámù;

39. ti Ṣúfámù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣúfámù;ti Húfámù, ìdílé àwọn ọmọ Húfámù.

40. Àwọn ọmọ Bẹ́là ní pasẹ̀ Árídì àti Náámánì nì yí:ti Árádì, ìdílé àwọn ọmọ Árádì;ti Náámánì, ìdílé àwọn ọmọ Náámánì.

41. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàáméjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ (45,600).

42. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dánì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Ṣúhámù, ìdílé àwọn ọmọ ṢúhámùWọ̀nyí ni ìdílé Dánì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

43. Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàáméjìlélọ́gbọ̀n ó lé irínwó (64,400).

44. Ti àwọn ọmọ Ásérì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Ímínà, ìdílé àwọn ọmọ Ímínà;ti Íṣífì, ìdílé àwọn ọmọ Íṣífì;ti Béríà, ìdílé àwọn ọmọ Béríà;

45. Ti àwọn ọmọ Béríà:ti Hébérì, ìdílé àwọn ọmọ Hébérì;ti Mákíẹ́lì, ìdílé àwọn ọmọ Mákíẹ́lì.

46. (Orúkọ ọmọ Áṣérì obìnrin nì jẹ́ Ṣérà.)

47. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Áṣérì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbéje (53,400).

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 26