Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 25:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Báyìí ni Ísírẹ́lì ṣe darapọ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì jọ ń sin Báálì ti Péórì. Ìbínú Olúwa sì ru sí wọn.

4. Olúwa sọ fún Mósè pé; “Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú Olúwa, kí ìbínú Olúwa lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì.”

5. Mósè sọ fún àwọn onídàájọ́ Ísírẹ́lì, “Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ pa arákùnrin rẹ̀ èyí tí ó darapọ̀ ní fífi orí balẹ̀ fún Báálì ti Peori.”

6. Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì sì mú obìnrin Mídíánì wá ṣíwájú ojú Mósè àti gbogbo ìpéjọ ti Ísírẹ́lì wọ́n sì ń sunkún ní àbáwọlé Àgọ́ Ìpàdé.

7. Nígbà tí Fínéhásì, ọmọ Élíásárì, ọmọ Árónì, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìpéjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.

8. Ó sì tẹ̀lé arákùnrin Ísírẹ́lì yìí lọ sínú àgọ́. Ó sì fi ọ̀kọ̀ gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ láti ara ọkùnrin Ísírẹ́lì àti sí ara obìnrin náà. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-àrùn lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dúró;

9. ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó kú nínú àjàkálẹ̀-àrùn náà jẹ́ ẹgbàá méjìlá. (24,000)

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 25