Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 23:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Móábù.

7. Nígbà náà ni Bálámù sọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ jáde wí pé:“Bálákì mú mi láti Árámù wá,ọba Móábù láti òkè ìlà oòrùn wáÓ wí pé, ‘Wá fi Jákọ́bù bú fún mi;wá, kí o sì jẹ́rì i sí Ísírẹ́lì.’

8. Báwo ní èmi ó ṣe fi búàwọn tí Ọlọ́run kò fi bú?Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wíàwọn tí Olúwa kò bá wí?

9. Láti ṣónṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn,láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n.Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀ èdè.

10. Ta ni ó lè ka eruku Jákọ́bùtàbí ka ìdámẹ́rin Ísírẹ́lì?Jẹ́ kí èmi kú ikú olóòtọ́,kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dàbí ti wọn!”

11. Bálákì sọ fún Bálámù pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀ta mi bú, Ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan Ṣùgbọ́n o bùkún wọn!”

12. Ó sì dáhùn wí pé, “Sé kí n má sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu?”

13. Nígbà náà Bálákì sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀ Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.”

14. Ó sì lọ sí pápá Ṣóímù ní orí òkè Písígà, ó sì kọ́ pẹpẹ méje síbẹ̀ ó sì fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

15. Bálámù ṣo fún Bálákì pé, “Dúró níbí ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ nígbà tí mo bá lọ pàdé rẹ̀ níbẹ.”

16. Olúwa pàdé Bálámù ó sì fí ọ̀rọ̀ sí ní ẹnu wí pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Bálákì kí o sì jísẹ́ fún un.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 23