Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 23:15-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Bálámù ṣo fún Bálákì pé, “Dúró níbí ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ nígbà tí mo bá lọ pàdé rẹ̀ níbẹ.”

16. Olúwa pàdé Bálámù ó sì fí ọ̀rọ̀ sí ní ẹnu wí pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Bálákì kí o sì jísẹ́ fún un.”

17. Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì báà tí ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Móábù. Bálákì sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni Olúwa wí?”

18. Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ:“Dìde, Bálákì;kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sípórà.

19. Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́,tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà.Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é?Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu-un ṣẹ?

20. Èmi gba àṣẹ láti bùkún;Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà.

21. “Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jákọ́bù,kò sì rí búburú kankan nínú Ísírẹ́lì. Olúwa Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn.Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn.

22. Ọlọ́run mú wọn jáde láti Éjíbítì wá,wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà.

23. Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jákọ́bù,tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Ísírẹ́lì.Nísinsìnyìí a ó sọ nípa ti Jákọ́bùàti Ísírẹ́lì, ‘Wo ohun tí Olúwa ti ṣe!’

24. Àwọn ènìyàn dìde bí abo kìnnìún;wọ́n dìde bí i kìnnìúntí kì í sinmi títí yóò fi pa ìkógún jẹtàbí mu ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó fi ara pa.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 23