Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 22:36-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Nígbà tí Bálákì gbọ́ pé Bálámù ń bọ̀ wá, ó jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀ ní ìlú Móábù tí ó wà ní agbégbé Ánónì, ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ̀.

37. Bálákì sì sọ fún Bálámù pé, “Ǹjẹ́ èmi kò a ránṣẹ́ kánjúkánjú sí ọ? Kí ló dé tí ìwọ kò fi wá sí ọ̀dọ̀ mi? Ṣé èmi kò tó láti sọ ọ́ di ẹni ńlá?”

38. “Kíyèsi, èmi ti wá sọ́dọ̀ rẹ nísinsin yìí,” Bálámù fẹ̀sì pé. “Ṣùgbọ́n ṣe mo lè sọ ohunkóhun? Mo gbọdọ̀ sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu.”

39. Nígbà náà Bálámù lọ pẹ̀lú Bálákì sí Kriati-Hosotíà.

40. Bálákì rú ẹbọ akọ màlúù pẹ̀lú àgùntàn, ó sì fún Bálámù ní díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.

41. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Bálákì gbé Bálámù lọ sí òkè Báálì, láti ibẹ̀ ló ti rí apákan àwọn ènìyàn.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 22