Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 22:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún Bálámù pé, “Má ṣe bá wọn lọ. Ìwọ kò gbọdọ̀ gé ègún lé àwọn ènìyàn náà lórí, nítorí a ti bùkún wọn.”

13. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Bálámù dìde ó sì sọ fún àwọn ìjòyè Bálákì pé, “Ẹ padà sí orílẹ̀ èdè yín, nítorí tí Olúwa ti kọ̀ láti jẹ́ kí n tẹ̀lé yín.”

14. Nígbà náà àwọn ìjòyè Móábù sì padà tọ Bálákì lọ wọ́n sì wí pé, “Bálámù kọ̀ láti tẹ̀lé wa.”

15. Nígbà náà Bálákì rán àwọn ìjòyè mìíràn tí wọ́n pọ̀ àwọn tí wọ́n sì níyì ju alákọ́kọ́ lọ.

16. Wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Bálámù wọ́n sì sọ pé:“Èyí ni ohun tí Bálákì ọmọ Sípórì sọ: Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun kí ó dè ọ́ lọ́nà láti wá sí ọ̀dọ̀ mi,

17. Nítorí pé èmi yóò fún ọ ní ẹ̀bùn dáradára màá sì ṣe ohunkóhun tí o bá sọ. Wá kí o sì wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú fún mi.”

18. Ṣùgbọ́n Bálámù dá wọn lóhùn pé, “Kó dà tí Bálákì bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, n kò ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí kéré tí o kọjá òfin Olúwa Ọlọ́run mi.

19. Nísinsìnyìí ẹ dúró níbí di ọjọ́ kejì gẹ́gẹ́ bí àwọn tókù ti ṣe nígbà náà èmi yóò mọ ohun tí Olúwa yóò tún sọ fún mi.”

20. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Ọlọ́run sì tọ Bálámù wá ó sì sọ wí pé, “Nígbà tí ọkùnrin yìí ti wá pè ọ́, lọ pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ẹnu nǹkan tí mo sọ fún ọ ni kí o ṣe.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 22