Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 2:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ẹ̀yà Símónì ni yóò pa ibùdó tẹ́lé wọn. Olórí Símónì ni Ṣélúmíélì ọmọ Surisadáì.

13. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje. (59,300).

14. Ẹ̀yà Gáádì ló tẹ̀lé wọn. Olórí Gáádì ni Eliásáfì ọmọ Déúélì.

15. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́ta (45,650).

16. Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Rúbẹ́nì, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rún ó lé àádọ́tàlélégbéje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 2