Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 19:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé:

2. “Èyí ni ohun tí òfin Olúwa pa láṣẹ béèrè lọ́wọ́ yín: Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọn mú ẹgbọrọ ọ̀dọ́ màlúù pupa tí kò lábùkù tàbí àbàwọ́n, tí kò sì tí ì ru ẹrù rí.

3. Ẹ mú fún Élíásárì àlùfáà, yóò sì mu jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó kí ó sì pa á ní ojú rẹ.

4. Nígbà náà ni Élíásárì àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí ìka ọwọ́ rẹ̀ yóò sì wọn lẹ́ẹ̀méje ní ọ̀kánkán iwájú àgọ́ ìpàdé.

5. Ní ojú rẹ̀ ni àlùfáà yóò ti sun ọ̀dọ́ abo màlúù yìí: awọ ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹran ara àti ìgbẹ́ rẹ̀.

6. Àlùfáà yóò mú igi òpépé, hísópù àti òwú òdòdó yóò sì jù wọ́n sí àárin ọ̀dọ́ abo màlúù tí a ń sun.

7. Lẹ́yìn náà, Àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ̀yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

8. Ẹni tí ó sun ún náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pèlú omi, òun náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títi di ìrọ̀lẹ́.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 19