Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 16:41-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Ní ọjọ́ kejì gbogbo ìjọ ènìyàn kùn sí Mósè àti Árónì pé, “Ẹ ti pa àwọn ènìyàn Olúwa.”

42. Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn péjọ lòdì sí Mósè àti Árónì, níwájú àgọ́ ìpàdé, lójijì ni ìkúùkù bolẹ̀, ògo Olúwa sì fara hàn.

43. Nígbà náà ni Mósè àti Árónì lọ ṣíwájú àgọ́ ìpàdé,

44. Olúwa sì sọ fún Mósè pé,

45. “Yàgò kúrò láàrin ìjọ ènìyàn yìí, kí ń ba le run wọ́n ní ìṣẹ́jú kan.” Wọ́n sì dojú bolẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 16