Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 16:24-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. “Sọ fún ìjọ ènìyàn pé, ‘Kí wọ́n jìnnà sí àgọ́ Kórà, Dátanì àti Ábírámù.’ ”

25. Mósè sì dìde lọ bá Dátanì àti Ábírámù àwọn olórí Ísírẹ́lì sì tẹ̀lé.

26. Ó sì kìlọ̀ fún ìjọ ènìyàn pé, “Ẹ kúrò ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú yìí! Ẹ má ṣe fọwọ́ kan ohun kan tí í ṣe tiwọn kí ẹ má ba à parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

27. Àwọn ènìyàn sì sún kúrò ní àgọ́ Kórà, Dátanì àti Ábírámù. Dátanì àti Ábírámù jáde, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ wọn sì dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn.

28. Nígbà náà ni Mósè wí pé, “Báyìí ni ẹ ó ṣe mọ̀ pé Olúwa ló rán mi láti ṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí àti pé kì í ṣe ìfẹ́ inú mi ni àwọn ohun tí mò ń ṣe.

29. Bí àwọn ènìyàn yìí bá kú bí gbogbo ènìyàn ti ń kú, bí ìrírí wọn kò bá sì yàtọ̀ sí ti àwọn ènìyàn yóòkù, a jẹ́ pé kì í ṣe Olúwa ló rán mi.

30. Ṣùgbọ́n bí Olúwa bá ṣe ohun túntún, tí ilẹ̀ sì la ẹnu, tó gbé wọn mì, àwọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní, tí wọ́n sì wọ inú ibojì wọn lọ láàyè, nígbà náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn yìí ti kẹ́gàn Olúwa.”

31. Bí ó sì ṣe parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ilẹ̀ pín sí méjì nísàlẹ̀ wọn,

32. ilẹ̀ sì lanu ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ará ilé wọn àti àwọn ènìyàn Kórà àti gbogbo ohun tí wọ́n ní.

33. Gbogbo wọn sì sọ̀kalẹ̀ sínú ibojì wọn láàyè pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n ní, ilẹ̀ sì padé mọ́ wọn, wọ́n sì ṣègbé kúrò láàrin ìjọ ènìyàn.

34. Nígbà tí àwọn yóòkù gbọ́ igbe wọn, wọ́n sálọ, wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ yóò gbé àwa náà mì pẹ̀lú.”

35. Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì run àádọ́tàlénígba ọkùnrin (250) tí wọ́n mú tùràrí wá.

36. Olúwa sọ fún Mósè pé,

37. “Sọ fún Élíásárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà, pé kí ó mú àwọn àwo tùràrí jáde kúrò nínú iná nítorí pé wọ́n jẹ́ mímọ́, kí ó sì tan iná náà káàkiri síbi tó jìnnà.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 16