Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 16:12-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Mósè sì ránṣẹ́ sí Dátanì àti Ábírámù àwọn ọmọ Élíábù. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé “Àwa kò ní í wá!

13. Kò ha tó gẹ́ ẹ́ pé o ti mú wa jáde láti ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin láti pa wá sínú ihà yìí? O tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di Olúwa lé wa lórí bí?

14. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ìwọ kò sì tí ì mú wa dé ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì pín ilẹ̀ ìní wa fún wa. Ìwọ ha fẹ́ sọ wá di ẹrú bí? Rárá o, àwa kò ní wá!”

15. Nígbà náà ni Mósè bínú gidigidi, ó sì sọ fún Olúwa pé, “Má ṣe gba ọrẹ wọn, èmi kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì pa ẹnikẹ́ni nínú wọn lára!”

16. Mósè sọ fún Kórà pé, “Ìwọ àti ọmọ lẹ́yìn rẹ gbọdọ̀ fara hàn níwájú Olúwa lọ́la—gbogbo yín, ìwọ, àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ àti Árónì.

17. Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín mú àwo tùràrí, kí ó sì fi tùràrí sínú rẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ àádọ́tàlénígba àwo tùràrí (250) kí ẹ sì ko wá ṣíwájú Olúwa. Ìwọ àti Árónì yóò mú àwo tùràrí wá pẹ̀lú.”

18. Nígbà náà ni oníkálukú wọn mú àwo tùràrí, wọ́n fi iná àti tùràrí sí i nínú, wọ́n sì dúró sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé, àwọn pẹ̀lú Mósè àti Árónì.

19. Nígbà tí Kórà kó gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé, ògo Olúwa sì farahan gbogbo ìjọ ènìyàn.

20. Olúwa sì sọ fún Mósè àti Árónì pé,

21. “Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọ̀nyí, kí ń ba à le pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.”

22. Ṣùgbọ́n Mósè àti Árónì dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, “Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mi gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣẹ̀?”

23. Olúwa tún sọ fún Mósè pé,

24. “Sọ fún ìjọ ènìyàn pé, ‘Kí wọ́n jìnnà sí àgọ́ Kórà, Dátanì àti Ábírámù.’ ”

25. Mósè sì dìde lọ bá Dátanì àti Ábírámù àwọn olórí Ísírẹ́lì sì tẹ̀lé.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 16