Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 15:32-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísirẹ́lì wà nínú ihà, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣa igi ní ọjọ́ Ísínmì.

33. Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣa igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mósè àti Árónì àti ṣíwájú gbogbo ìjọ ènìyàn;

34. Wọ́n fi sí ìpamọ́ nítorí pé ohun tí wọn ó ṣe fún un kò tí ì yé wọn.

35. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Kíkú ni ọkùnrín náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sọ ọ́ lókúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó.”

36. Wọ́n mú un jáde sí ẹ̀yìn ibùdó, gbogbo ìjọ ènìyàn sì sọ ọ́ lókúta pa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

37. Olúwa sọ fún Mósè pé,

38. “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sọ fún wọn pé: ‘Títí dé àwọn ìran tó ń bọ̀ ni kí wọn máa ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn, kí wọn sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ búlúù sí wajawaja kọ̀ọ̀kan.

39. Wajawaja yìí ni ẹ sì máa wò láti lè mú yín rántí gbogbo òfin Olúwa, kí ẹ bá à lè ṣe wọ́n, kí ẹ sì má bá à ṣe àgbérè nípa títẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àti ojú yín.

40. Nígbà náà ni ẹ ó gbọ́ran láti pa gbogbo òfin mi mọ́, ẹ ó sì jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run yín.

41. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti Éjíbítì láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 15