Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 15:13-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ yín ni kí ó máa se àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí ó bá mú ọrẹ àfinásun gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn wá fún Olúwa.

14. Bí àléjò kan bá ń gbé láàrin yín ní gbogbo ìran yín, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ mú ọrẹ àfinásun bí òórùn dídùn wá fún Olúwa, gbogbo bí ẹ bá ṣe ń ṣe náà ni kí ó ṣe.

15. Gbogbo ìjọ ènìyàn gbọdọ̀ ní òfin kan náà fún ọmọ bíbí ilẹ̀ yín àti fún àwọn àlejò tó ń gbé láàrin yín, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún àwọn ìran tó ń bọ̀. Ẹ̀yin àti àlejò tó ń gbé láàrin yín sì jẹ́ bákan náà níwájú Olúwa:

16. Òfin kan àti ìlànà kan ni yóò wà fún yín àti fún àwọn àlejò tí ń gbé láàrin yín.’ ”

17. Olúwa sọ fún Mósè pé,

18. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísirẹ́lì pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mo ń mú yín lọ.

19. Tí ẹ sì jẹ oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ mú nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè wá fún Olúwa.

20. Ẹ mú àkàrà wá nínú àkọ́so oúnjẹ yín wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè sí Olúwa, ọrẹ láti inú ilẹ̀ ìpakà yín.

21. Nínú àkọ́so oúnjẹ yín ni kí ẹ ti máa mú ọrẹ ìgbésókè yìí fún Olúwa.

22. “ ‘Bí ẹ bá kùnà láìròtẹ́lẹ̀ láti pa àwọn òfin tí Olúwa fún Mósè mọ́:

23. Èyí ni gbogbo òfin tí Olúwa fún yín láti ẹnu Mósè láti ọjọ́ tí Olúwa ti fún yín àti títí dé ìran tó ń bọ̀.

24. Bí ẹ̀ṣẹ̀ bá wáyé láìròtẹ́lẹ̀ láì jẹ́ pé ìjọ ènìyàn mọ̀ sí i, nígbà náà ni kí gbogbo ìjọ ènìyàn mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan wá fún ẹbọ sísun bí òórùn dídùn sí Olúwa, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà, pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

25. Àlùfáà yóò sì se ètùtù, fun gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì, a ó sì dárí jìn wọ́n, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti mú ọrẹ àfinásun wá fún Olúwa nítori ẹ̀sẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 15