Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 14:26-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé:

27. “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ìjọ ènìyàn búburú yìí yóò fi máa kùn sími? Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kùn sí mi.

28. Sọ fún wọn, Bí Mo ti wà láàyè nítòótọ́ ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ wí létí mi ni èmi ó ṣe fún un yín.

29. Nínú ihà yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yín tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 14