24. Ṣùgbọ́n nítorí pé Kélẹ́bù ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mi ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀.
25. Níwọ̀n ìgbà tí àwọn ará Ámálékì àti àwọn ará Kénánì ń gbé ní àfonífojì, ẹ yípadà lọ́la kí ẹ sì dojú kọ ihà lọ́nà Òkun Pupa.”
26. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé:
27. “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ìjọ ènìyàn búburú yìí yóò fi máa kùn sími? Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kùn sí mi.
28. Sọ fún wọn, Bí Mo ti wà láàyè nítòótọ́ ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ wí létí mi ni èmi ó ṣe fún un yín.
29. Nínú ihà yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yín tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà.
30. Ọ̀kan nínú yín kò ní í dé ilẹ̀ tí mo búra láti fi ṣe ilẹ̀ yín, àyàfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè àti Jósúà ọmọ Núnì.
31. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ yín tí ẹ wí pé wọn ó di ìjẹ, àwọn ni n ó mú dé bẹ̀ láti gbádùn ilẹ̀ tí ẹ kọ̀ sílẹ̀.
32. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, òkú yín yóò ṣubú ní ihà yìí.