Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Éṣíkólù, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èṣo àjàrà gíréèpù kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èṣo pomegíránétì àti èṣo ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú.