Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 13:13-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Láti inú ẹ̀yá Áṣérì, Ṣétúrì ọmọ Míkáẹ́lì.

14. Láti inú ẹ̀yà Náfítanì, Nábì ọmọ Fófósì;

15. Láti inú ẹ̀yà Gádì, Géúlì ọmọ Mákì.

16. Wọ̀nyí ni orukọ àwọn ènìyàn tí Mósè rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Ósísà ọmọ Núnì ni Mósè sọ ní Jóṣúà.)

17. Nígbà tí Mósè rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà Gúúsù lọ títi dé àwọn ìlú olókè

18. Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré.

19. Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi?

20. Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èṣo àjàrà gíréépù.)

21. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti Aginjù Ṣínì títí dé Réhóbù lọ́nà Lébò Hámátì.

22. Wọ́n gba Gúsù lọ sí Hébírónì níbi tí Áhímánì, Ṣésáì àti Tálímà tí í se irú ọmọ Ánákì ń gbé. (A ti kọ́ Hébúrónì ní ọdun méje ṣáájú Ṣánì ní Éjíbítì.)

23. Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Éṣíkólù, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èṣo àjàrà gíréèpù kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èṣo pomegíránétì àti èṣo ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú.

24. Wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní àfonífojì Ésíkólù nítorí ìdí èso gíréépù tí wọ́n gé níbẹ̀.

25. Wọ́n padà sílé lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí wọ́n ti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.

26. Wọ́n padà wá bá Mósè àti Árónì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísiréli ní ijù Kádésí Páránì. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n.

27. Wọ́n sì fún Mósè ní ìròyìn báyìí: “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóótọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èṣo ibẹ̀ nìyìí.

28. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tó ń gbé níbẹ̀ lágbára, àwọn ìlú náà jẹ́ ìlú olódi bẹ́ẹ̀ ni ó sì tóbi púpọ̀. A tilẹ̀ rí àwọn irú ọmọ Ánákì níbẹ̀.

29. Àwọn Ámálékì ń gbé ní ilẹ̀ Gúsù; àwọn ará Hítì, àwọn ará Jébúsì àti àwọn ará Ámórì ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kénánì sì ń gbé ẹ̀bá òkun àti ní etí bèbè Jọ́dánì.”

30. Kélẹ́bù sì pa àwọn ènìyàn náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mósè, ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ lẹ́ẹ̀kan náà láti lọ gba ilẹ̀ náà, nítorí pé àwa le è gbà á.”

31. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ gòkè lọ yẹ ilẹ̀ wò sọ pé, “Àwa kò le gòkè lọ bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí nítorí pé wọ́n lágbára jù wá lọ.”

32. Báyìí ni wọ́n ṣe mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ tí wọ́n lọ yẹ̀ wò. Wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ tí a lọ yẹ̀ wò jẹ́ ilẹ̀ tí ń run àwọn olùgbé ibẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn tí a rí níbẹ̀ jẹ́ ènìyàn tó fìrìgbọ̀n tó sì sígbọnlẹ̀.

33. A sì tún rí àwọn òmìrán (irú àwọn ọmọ Ánákì) àwa sì rí bí i kòkòrò tata ní ojú ara wa, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà sì rí ní ojú wọn.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 13