Nọ́ḿbà 11:25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ìkúùkù ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lárá Ẹ̀mí tó wà lára Mósè sí ara àwọn àádọ́rin (70) àgbààgbà náà, Ó sì sẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n ṣọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò ṣọtẹ́lẹ̀ mọ́.