Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 11:23-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Olúwa sì dá Mósè lóhùn pé, “Ọwọ́ Olúwa ha kúrú bí? Ìwọ yóò ri nísinsin yìí bóyá ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò ṣẹ tàbí kò ni í ṣẹ.”

24. Mósè sì jáde, ó sọ ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn. Ó mú àwọn àádọ́rin (70) àgbààgbà Ísírẹ́lì dúró yí àgọ́ ká.

25. Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ìkúùkù ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lárá Ẹ̀mí tó wà lára Mósè sí ara àwọn àádọ́rin (70) àgbààgbà náà, Ó sì sẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n ṣọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò ṣọtẹ́lẹ̀ mọ́.

26. Àwọn ọkùnrin méjì, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Élídádì àti Médádì kò kúrò nínú àgọ́. Orúkọ wọn wà lára àádọ́rin (70) àgbààgbà yìí ṣùgbọ́n wọn kò jáde nínú àgọ́ ṣíbẹ̀ Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sì ṣọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́.

27. Ọmọkùnrin kan sì sáré lọ sọ fún Mósè pé, “Élídádì àti Médádì ń ṣọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́.”

28. Jósúà ọmọ Núnì tí í ṣe ìránṣẹ́ Mósè, láti kékeré tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dáhùn pé, “Mósè olúwa mi, dá wọn lẹ́kun!”

29. Mósè sì wí fún un pé, “Àbí ìwọ ń jowú nítorí mi? Ìbá ti wù mí tó, kí gbogbo àwọn ènìyàn Olúwa jẹ́ wòlíì, kí Olúwa si fi Ẹ̀mí rẹ̀ sí wọn lára!”

30. Mósè àti àwọn àgbààgbà yìí sì padà sínú àgọ́.

31. Afẹ́fẹ́ sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì kó àparò wá láti inú òkun. Ó sì dà wọ́n káàkiri gbogbo ibùdó ní ìwọ̀n gíga ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta sórí ilẹ̀, bí ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan ní gbogbo àyíká.

32. Ní gbogbo ọjọ́ náà àti òru, títí dé ọjọ́ kejì ni àwọn ènìyàn fi ń kó àparò yìí: Ẹni tó kó kéré jù lọ kó ìwọ̀n hómérì mẹ́wáà, wọ́n sì sà wọ́n sílẹ̀ fún ara wọn yí gbogbo ibùdó.

33. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹran náà sì wà láàrin eyín wọn, kó tó di pé wọ́n jẹ ẹ́, ìbínú Olúwa sì ru sí àwọn ènìyàn, ó sì pa wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn.

34. Torí èyí ni wọ́n ṣe pe ibẹ̀ ní Kíbírótì Hátafà nítorí pé níbẹ̀ ni wọ́n gbé sìnkú àwọn ènìyàn tó ní ọ̀kánjúà oúnjẹ sí.

35. Àwọn ènìyàn yóòkù sì gbéra láti Kíbírótì Hátafà lọ pa ibùdó sí Hásérótì wọ́n sì dúró nibẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 11