Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 11:11-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Mósè sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, “Kí ló dé tí o fi mú wàhálà yìí bá iráńṣẹ́ rẹ? Kí ni mo ṣe tí n kò fi tẹ ọ lọ́rùn tí ìwọ fi di ẹrù àwọn ènìyàn wọ̀nyí lé mi lórí.

12. Èmi ni mo ha lóyún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí bí? Àbí èmi ló bí wọn? Tí ìwọ fi sọ fún mi pé, máa gbé wọn sí oókan àyà rẹ, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti máa ń gbe ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti búra láti fún àwọn bàbá ńlá wọn.

13. Níbo ni n ó ti rí ẹran fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Nítorí wọ́n ń sunkún sí mi pé, ‘Fún wa lẹ́ran jẹ́!’

14. Èmi nìkan kò lè dá gbé wàhálà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹrù wọn ti wúwo jù fún mi.

15. Bí ó bá sì ṣe pé báyìí ni ìwọ ó ṣe máa ṣe fún mi, kúkú pa mí báyìí, tí mo bá ti bá ojú rere rẹ pàdé—kí ojú mi má ba à rí ìparun mi.”

16. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé: “Mú àádọ́rin (70) ọkùnrin nínú àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn tí o mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí àti olóyè láàrin àwọn ènìyàn wá sínú Àgọ́ Ìpàdé, kí wọ́n lé dúró níwájú mi.

17. Èmi ó sì sọ̀kalẹ̀ wá bá yín sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Èmi ó sì mú nínú Ẹ̀mi tí ń bẹ lára rẹ láti fi sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru àjàgà àwọn ènìyàn kí ó má ṣe pé ìwọ nìkan ni ó o máa ru àjàgà náà.

18. “Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé: ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀la, ẹ ó sì jẹ ẹran. Nítorí pé Olúwa ti gbọ́ igbe ẹkún yín, èyí tí ẹ sun pé, “Ìbá ṣe pé a lè rí ẹran jẹ ni! Ó sàn fún wa ní Éjíbítì jù báyìí lọ!” Nítorí náà ni Olúwa yóò fi fún yín ní ẹran, ẹ ó sì jẹ ẹ́.

19. Ẹ kò ní i jẹ ẹ́ fún ọjọ́ kan, ọjọ́ méjì, ọjọ́ márùn-ún, ọjọ́ mẹ́wàá tàbí ogúnjọ́ lásán,

20. Ṣùgbọ́n fún odidi oṣù kan: títí tí ẹran náà yóò fi máa yọ ní imú yín, tí yóò sì sú yín: nítorí pé ẹ ti kẹ́gàn Olúwa tí ó wà láàrin yín, ẹ sì ti sunkún fún un wí pé, “Kí ló dé tí a fi kúrò ní Éjíbítì gan-an?” ’ ”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 11