Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 11:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ènìyàn ń ṣe àròyé nípa wàhálà wọn sí etíìgbọ́ Olúwa. Ìbúnú Olúwa sì ru sókè nígbà tí ó gbọ́ àròyé yìí, Nígbà náà ni iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa bọ́ sí àárin wọn, ó sì run àwọn tó wà ní òpin ibùdó.

2. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn kígbe sí Mósè, Mósè sì gbàdúrà sí Olúwa iná náà sì kú.

3. Wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Tàbérà torí pé iná láti ọ̀dọ̀ Olúwa jó láàrin wọn.

4. Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí tó wà láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́kúfẹ́ wọn fi ìtara bèèrè fún oúnjẹ mìíràn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún wí pé, “Bí i pé kí á rí ẹran jẹ báyìí!

5. Àwa rántí ẹja tí à ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ ní Éjíbítì, apálá, ègúsí, ewébẹ̀ àlùbọ́sà àti àwọn ẹ̀fọ́ mìíràn

6. Ṣùgbọ́n báyìí gbogbo ara wa ti gbẹ, kò sí ohun mìíràn láti jẹ àfi mánà nìkan tí a rí yìí!”

7. Mánà náà dàbí èso koriáńdérì, ìrísí rẹ̀ sì dàbí oje igi.

8. Àwọn ènìyàn náà ń lọ káàkiri láti kó o, wọn ó lọ̀ ọ́ lórí ọlọ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó. Wọ́n le ṣè é nínú ìkòkò tàbí kí wọn ó fi ṣe àkàrà, adùn rẹ̀ yóò sì dàbí adùn ohun tí a fi òróró ṣe.

9. Nígbà tí ìrì bá ṣẹ̀ sí ibùdó lórí ni mánà náà máa ń bọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 11