Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 1:31-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Ṣébúlúnì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógún-ó-lé-egbéje (57,400).

32. Láti inú àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù:Láti ìran Éfúráímù:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

33. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Éfúráímù jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

34. Láti ìran Mánássè:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

35. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Mánásè jẹ́ ẹgbàá ẹ́rìndínlógún-ó-lé-igba (32,200).

36. Láti ìran Bẹ́ńjámínì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

37. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógún-ó-lé-egbéje (35,400).

38. Láti ìran Dánì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

39. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dánì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n-ó-lé-ẹẹ̀dẹ́gbẹ̀rin (62,700).

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 1