Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 1:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Mósè àti Árónì mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí

18. wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Ísírẹ́lì jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì se àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè,

19. gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paṣẹ fún Mósè. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú ihà Ṣínáì.

20. Láti ìran Rúbẹ́nì tí í se àkọ́bí Ísírẹ́lì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

21. Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Rúbẹ́nì jẹ́ ẹgbàá mẹ́talélọ́gbọ̀n-ó-lé-ẹgbẹ̀ta (46,500).

22. Láti ìran Símónì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

23. Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀ya Símónì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún-ó-lé ọ̀ọ́dúnrún (59,300).

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 1