Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 9:5-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Léfì: Jéṣúà, Bánì, Háṣábínéáyà, Ṣérébáyà, Hódáyà, Ṣébánáyà àti Pétaíáyà—wí pé: “Ẹ dìde ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó wà láé àti láéláé.”“Ìbùkún ni fún orúkọ ọ̀ rẹ tí ó ní ògo, kí ó sì di gbígbéga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ.

6. Ìwọ nìkan ni Olúwa. Ìwọ ni ó dá àwọn ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù àti àìlónkà ogun ọ̀run wọn, ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú un rẹ̀, àwọn òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú un wọn. Ìwọ fún gbogbo wọn ní ìyè àìlónkà àwọn ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́.

7. “Ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run, tí ó yan Ábúrámù tí ó sì mú u jáde láti Úrì ti Kálídéà, tí ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ábúráhámù.

8. Ìwọ sì rí í pé ọkàn rẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí ọ, ìwọ sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú u rẹ̀ láti fi ilẹ̀ àwọn aráa Kénánì, Hítì, Ámórì, Pérísì, Jébúsì àti Gírígásì fún irú àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwọ ti pa ìpinnu rẹ̀ mọ́ nítorí tí ìwọ jẹ́ olódodo.

9. “Ìwọ rí ìpọ́njú àwọn baba ńlá wa ní Éjíbítì; ìwọ gbọ́ igbe ẹkún un wọn ní òkun pupa.

10. Ìwọ rán iṣẹ́ àmì àti isẹ́ ìyanu sí Fáráò, sí gbogbo àwọn ìjòyèe rẹ̀ àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ẹ rẹ̀, nítorí ìwọ mọ ìwà ìgbéraga tí àwọn ará Éjíbítì hù sí wọn. Ìwọ ra orúkọ fún araà rẹ, èyí tí ó sì wà títí di òní yìí.

11. Ìwọ pín òkun níwájúu wọn, nítorí kí wọn lè kọjá ní ìyàngbẹ ilẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ sọ àwọn tí ń lépa wọn sínú ibú, bí òkúta sínú omi ńlá.

12. Ní ọ̀sán ìwọ daríi wọn pẹ̀lú òpó ìkúùkú àti ní òru ni ìwọ daríi wọn pẹ̀lú òpó iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọn yóò gbà.

13. “Ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá sí orí òkè Ṣínáì; ìwọ bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. Ìwọ fún wọn ní ìlànà àti àwọn òfin tí ó jẹ́ òdodo tí ó sì tọ́ àti ìlànà tí ó dára.

14. Ìwọ mú ọjọ́ Ìsinmi rẹ mímọ́ di mímọ̀ fún wọn, o sì fún wọn ní àwọn ìlànà, àwọn àṣẹ àti àwọn òfin láti ọwọ́ọ Mósè ìránṣẹ́ẹ̀ rẹ.

15. Ìwọ fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n àti nígbà òrùngbẹ o fún wọn ní omi láti inú àpáta; ó sì sọ fún wọn pé, kí wọ́n lọ láti lọ gba ilẹ̀ náà tí ìwọ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fi fún wọn.

Ka pipe ipin Nehemáyà 9