Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 9:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kan náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì péjọ pọ̀, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da eruku sórí ara wọn.

2. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ya ara wọn ṣọ́tọ̀ kúrò nínú un gbogbo àwọn àlejò. Wọ́n dúró ní ààyè e wọn, wọ́n sì ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn àti iṣẹ́ búburú àwọn baba wọn.

3. Wọ́n dúró sí ibi tí wọ́n wà, wọ́n sì fi ìdámẹ́rin ọjọ́ kà nínú ìwé òfin Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì tún fi ìdámẹ́rin mìíràn ní ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ní ṣíṣin Olúwa Ọlọ́run wọn.

4. Nígbà náà ni Jéṣúà, àti Bánì, Kádímíélì, Ṣebaníà, Bunnì, Ṣeribíà, Bánì àti Kénánì gòkè dúró lórí àwọn àtẹ̀gùn àwọn ọmọ Léfì, wọ́n si fi ohùn rara kígbe sí Olúwa Ọlọ́run wọn

5. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Léfì: Jéṣúà, Bánì, Háṣábínéáyà, Ṣérébáyà, Hódáyà, Ṣébánáyà àti Pétaíáyà—wí pé: “Ẹ dìde ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó wà láé àti láéláé.”“Ìbùkún ni fún orúkọ ọ̀ rẹ tí ó ní ògo, kí ó sì di gbígbéga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ.

6. Ìwọ nìkan ni Olúwa. Ìwọ ni ó dá àwọn ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù àti àìlónkà ogun ọ̀run wọn, ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú un rẹ̀, àwọn òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú un wọn. Ìwọ fún gbogbo wọn ní ìyè àìlónkà àwọn ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́.

7. “Ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run, tí ó yan Ábúrámù tí ó sì mú u jáde láti Úrì ti Kálídéà, tí ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ábúráhámù.

8. Ìwọ sì rí í pé ọkàn rẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí ọ, ìwọ sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú u rẹ̀ láti fi ilẹ̀ àwọn aráa Kénánì, Hítì, Ámórì, Pérísì, Jébúsì àti Gírígásì fún irú àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwọ ti pa ìpinnu rẹ̀ mọ́ nítorí tí ìwọ jẹ́ olódodo.

9. “Ìwọ rí ìpọ́njú àwọn baba ńlá wa ní Éjíbítì; ìwọ gbọ́ igbe ẹkún un wọn ní òkun pupa.

Ka pipe ipin Nehemáyà 9