Ẹ́sírà sí ìwé náà, gbogbo ènìyàn sì le rí í nítorí ó dúró níbi tí ó ga ju gbogbo ènìyàn lọ; bí ó sì ti sí ìwé náà, gbogbo ènìyàn dìde dúró.