Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 2:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní oṣù Níṣánì (oṣù kẹrin) ní ogún ọdún ìjọba ọba Aritaṣéṣéṣì, nígbà tí a gbé wáìnì wá fún-un, mo gbé wáìnì náà mo fi fún ọba, Ìbànújẹ́ kò hàn ní ojú mi rí ní iwájúu rẹ̀.

2. Nítorí náà ni ọba béèrè lọ́wọ́ mi pé “Èéṣe tí ojú rẹ fi fàro nígbà tí kò rẹ̀ ọ́? Èyí kì í ṣe ohun mìíràn bí kò ṣe ìbànújẹ́ ọkàn”Ẹ̀rù bà mí gidigidi,

3. Ṣùgbọ́n mo wí fún ọba pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! È é ṣe tí ojú mi ko ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí a sin àwọn baba mi sí wà ní ahoro, tí a sì ti fi iná run àwọn ibodè rẹ̀?”

4. Ọba wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”Nígbà náà, ni mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run,

5. mo sì dá ọba lóhùn pé, “Ti ó bá wu ọba, tí ìránṣẹ́ rẹ bá sì rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí ó rán mi lọ sí ìlú náà ní Júdà ní bi tí a sin àwọn baba mi nítorí kí èmi lè tún un kọ́.”

Ka pipe ipin Nehemáyà 2