Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 13:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Mo sì fi àlùfáà Ṣelemáyà, Ṣádókà akọ̀wé àti ọmọ Léfì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pedáyà ṣe alákóṣo àwọn yàrá ìkó—nǹkan sí. Mo sì yan Hánánì ọmọ Ṣákúrì, ọmọ Mátanáyà bí olùrànlọ́wọ́ọ wọn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a kà sí àwọn tó ṣé e gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn ni a yàn láti máa pín ohun èlò fún àwọn arákùnrin wọn.

14. Rántíì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o má sì ṣe gbàgbé ohun tí mo fi òtítọ́ ṣe fún ilé Ọlọ́run mi yìí àti fún iṣẹ́ ẹ rẹ̀ gbogbo.

15. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Júdà tí wọ́n ń fún wáìnì ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé oríi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù. Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà.

16. Àwọn ará Tírè ti ń gbé nínú un Jérúsálẹ́mù ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù àti fún àwọn ọmọ Júdà.

17. Mo bá àwọn ọlọ́lá Júdà wí, mo wí fún wọn pé, “Èwo ni ohun búburú tí ẹ ń ṣe yìí ti ẹ ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.

18. Ṣé àwọn baba ńlá yín kòha ti ṣe nǹkan kan náà tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo àjálù yìí wá oríi wa, àti sórí ìlú yìí? Báyìí, ẹ̀yin tún ń ru ìbínú ṣókè síi sórí Ísírẹ́lì nípa bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.”

19. Nígbà tí ojú ọjọ́ ń bora ní ẹnu ibodè Jérúsálẹ́mù, ṣáájú ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí a ti àwọn ìlẹ̀kùn, kí wọn má sì sí i títí tí ọjọ́ ìsinmi yóò fi kọjá. Mo yan àwọn ìránṣẹ́ẹ̀ mi láti ṣọ́ ẹnu ibodè, kí a má ba à lè gbé ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi.

20. Ṣíbẹ̀, àwọn tí ń tà àti àwọn tí ń rà sùn ẹ̀yìn odi Jérúsálẹ́mù ní ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀méjì.

21. Ṣùgbọ́n mo kìlọ̀ fún wọn pé, “È é tí jẹ́ ti ẹ̀yin fi ń sùn ní ẹ̀yin odi ní òru? Bí ẹ̀yìn bá tún dán an wò mọ́, èmi yóò fi ọwọ́ líle mú un yín.” Láti ọjọ́ náà lọ, wọn kò sì wá ní ọjọ́ ìsinmi mọ́.

22. Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì pé kí wọn ya ara wọn sí mímọ́, kí wọn sì ṣọ́ ẹnu ibodè kí a lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.Tún rántíì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o sì fi àánú un rẹ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí i títóbi ìfẹ́ẹ̀ rẹ.

Ka pipe ipin Nehemáyà 13