Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 13:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ náà ni a ka ìwé Móṣè ṣókè sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn, nínú un rẹ̀ ni a ti rí i tí a kọ ọ́ sílẹ̀ pé a kò gbọdọ̀ gba àwọn aráa Ámónì tàbí àwọn aráa Móábù sí àárin ìjọ ènìyàn Ọlọ́run láéláé.

2. Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Bálámù ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn-ún lé wọn lórí (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún).

3. Nígbà tí àwọn ènìyàn gbọ́ òfin yìí, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjòjì ènìyàn tí ó dara pọ̀ mọ́ wọn kúrò láàrin àwọn Ísírẹ́lì.

4. Ṣáájú èyí a ti fi Élíáṣíbù àlùfáà ṣe alákoṣo yàrá ìkó nǹkan ilé Ọlọ́run wa sí. Ó súnmọ́ Tóbíyà pẹ́kípẹ́ki.

5. Ó sì ti pèsè yàrá ńlá kan fún un, èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀ fún ìtọ́jú ọrẹ ọkà, tùràrí àti àwọn ohun èlò tẹ́ḿpìlì àti ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró ti a fi lélẹ̀ bí ìlànà fún àwọn ọmọ Léfì, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà àti pẹ̀lúu gbogbo ọrẹ fún àwọn àlùfáà.

6. Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo èyí ń lọ lọ́wọ́, èmi kò sí ní Jérúsálẹ́mù, nítorí pé ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n Aritaṣéṣéṣì ọba Bábílónì ni mo padà tọ ọba lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀, mo gba ààyè lọ́dọ̀ọ rẹ̀.

7. Mo sì padà sí Jérúsálẹ́mù. Níhìn-ín ni mo ti mọ̀ nípa onírúurú ohun búburú tí Élíásíbù ti ṣe ní ti pípèṣè yàrá fún Tóbíyà nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run.

8. Kò tẹ́ mi lọ́rùn rárá, mo kó gbogbo ohun èlò ìdílée Tóbíyà dà síta láti inú iyàrá náà.

9. Mo pàṣẹ kí wọn ya àwọn iyàrá náà sí mímọ́, mo sì kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run padà síbẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti tùràrí.

10. Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Léfì, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ẹ wọn.

11. Nígbà náà ni mo bá àwọn ìjòyè wí, mo sì béèrè lọ́wọ́ọ wọn pé, “Èéṣe tí a fi kọ ilé Ọlọ́run sílẹ̀?” Nígbà náà ni mo pè wọ́n jọ pọ̀, mo sì fi olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀.

12. Gbogbo Júdà mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó—nǹkan sí.

13. Mo sì fi àlùfáà Ṣelemáyà, Ṣádókà akọ̀wé àti ọmọ Léfì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pedáyà ṣe alákóṣo àwọn yàrá ìkó—nǹkan sí. Mo sì yan Hánánì ọmọ Ṣákúrì, ọmọ Mátanáyà bí olùrànlọ́wọ́ọ wọn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a kà sí àwọn tó ṣé e gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn ni a yàn láti máa pín ohun èlò fún àwọn arákùnrin wọn.

14. Rántíì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o má sì ṣe gbàgbé ohun tí mo fi òtítọ́ ṣe fún ilé Ọlọ́run mi yìí àti fún iṣẹ́ ẹ rẹ̀ gbogbo.

15. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Júdà tí wọ́n ń fún wáìnì ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé oríi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù. Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà.

16. Àwọn ará Tírè ti ń gbé nínú un Jérúsálẹ́mù ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù àti fún àwọn ọmọ Júdà.

17. Mo bá àwọn ọlọ́lá Júdà wí, mo wí fún wọn pé, “Èwo ni ohun búburú tí ẹ ń ṣe yìí ti ẹ ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.

Ka pipe ipin Nehemáyà 13