Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Náhúmù 1:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ nípa Nínéfè. Ìwé ìran Náhúmù ará Elikósì.

2. Olúwa ń jowu, ó sì ń gbẹ̀san. Olúwa ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú Olúwa ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀,Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀

3. Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára; Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láì jìyà.Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú ààjà àti nínú ìjì,Ìkùùku sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.

4. Ó bá òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ;Ó sí sọ gbogbo odò di gbígbẹ.Báṣánì àti Kámẹ́lì sì rọ,Ìtànná Lébánónì sì rẹ̀ sílẹ̀.

5. Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀,àwọn òkè kéékèèkéé sì di yíyọ́,ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀,àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

6. Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀?Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀?Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná;àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀.

7. Rere ni Olúwa,ààbò ní ọjọ ìpọ́njú.Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé e,

8. Ṣùgbọn pẹ̀lú ìkún omi ńlání òun yóò fi ṣe ìparun ibẹ̀ dé òpin;òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀.

9. Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ lòdì sí Olúwa?Òun yóò fi òpin sí i,Ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì

10. Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣùwọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọna ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àkékù koríko gbígbẹ

11. Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Nínéfè, ni ẹnìkan ti jáde wátí ó ń gbérò ibi sí Olúwati ó sì ń gbìmọ̀ búburú.

Ka pipe ipin Náhúmù 1