Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Míkà 2:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Tí òpùrọ́ àti ẹlẹ́tàn bá wà tí wọ́n sì wí pé,‘Èmi yóò sọ tẹ́lẹ̀ fún ọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wáìnì àti bíà,’òun ni yóò tilẹ̀ ṣe wòlíì àwọn ènìyàn wọ̀nyí!

12. “Èmi yóò kó gbogbo yín jọ, ìwọ Jákọ́bù;Èmi yóò gbá ìyókù Ísírẹ́lì jọ.Èmi yóò kó wọn jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú agbo ẹran,gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nínú agbo wọn,ibẹ̀ yóò sì pariwo nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn.

13. Ẹni tí ó ń fọ ọ̀nà yóò lọ sókè níwájú wọn;Wọn yóò fọ láti ẹnu-bodè, wọn yóò sì jáde lọ.Àwọn ọba wọn yóò sì kọjá lọ níwájú wọn, Olúwa ni yóò sì ṣe olórí wọn.”

Ka pipe ipin Míkà 2