Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Málákì 4:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, òòrùn ododo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúlárada ni ìyẹ́ apá rẹ̀. Ẹ̀yin yóò sì jáde lọ, ẹ̀yin yóò sì máa fò fún ayọ̀ bi àwọn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù tí a tú sílẹ̀ lórí ìso.

3. Ẹ̀yin yóò sì tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀: nítorí wọn yóò di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ náà tí èmi yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

4. “Ẹ rántí òfin Mósè ìránṣẹ́ mi, àwọn ìlànà àti òfin èyí tí mo fún un ní Hórébù fún gbogbo Ísírẹ́lì.”

5. “Wò ó, èmi yóò rán wòlíì Èlíjà sí i yín, ki ọjọ́ ńlá, ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa to dé:

6. Òun yóò sì pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sì ti àwọn baba wọn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò wá, èmi yóò sì fi ilẹ̀ náà gégùn-ún.”

Ka pipe ipin Málákì 4