Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Málákì 4:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Dájúdájú, ọjọ́ náà ń bọ̀; tí yóò máa jó bi iná ìléru. Gbogbo àwọn agbéraga, àti gbogbo àwọn olùṣe búburú yóò dàbí àgékù koríko: ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò si jó wọn run,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, “Ti ki yóò fi kù gbòǹgbò kan tàbí ẹ̀ka kan fún wọn.

2. Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, òòrùn ododo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúlárada ni ìyẹ́ apá rẹ̀. Ẹ̀yin yóò sì jáde lọ, ẹ̀yin yóò sì máa fò fún ayọ̀ bi àwọn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù tí a tú sílẹ̀ lórí ìso.

3. Ẹ̀yin yóò sì tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀: nítorí wọn yóò di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ náà tí èmi yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

4. “Ẹ rántí òfin Mósè ìránṣẹ́ mi, àwọn ìlànà àti òfin èyí tí mo fún un ní Hórébù fún gbogbo Ísírẹ́lì.”

Ka pipe ipin Málákì 4