Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 9:17-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ó tún mu ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní àfikún ẹbọ sísun tí àárọ̀.

18. Ó pa akọ màlúù àti àgbò bí ẹbọ àlàáfíà fún àwọn ènìyàn. Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà fún un, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká.

19. Ṣùgbọ́n ọ̀rá akọ màlúù àti àgbò náà: ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, básí ọ̀rá, ọ̀rá kíndìnrín, àti ọ̀rá tó bo ẹ̀dọ̀:

20. gbogbo rẹ̀ ni wọ́n kó lórí igẹ̀ ẹran náà. Árónì sì sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ.

21. Árónì fí igẹ̀ àti itan ọ̀tún ẹran náà níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì bí Mósè ṣe pa á láṣẹ.

22. Árónì sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn ènìyàn, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn tó sì ti rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà, ó sọ̀kalẹ̀.

23. Mósè àti Árónì sì wọ inú àgọ́ ìpàdé. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn ènìyàn, ògo Olúwa sì farahàn sí gbogbo ènìyàn,

24. Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó ẹbọ sísun àti ọ̀rá orí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì rí èyí wọ́n hó ìhó ayọ̀, wọ́n sì dojú bolẹ̀.

Ka pipe ipin Léfítíkù 9