Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 9:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kẹjọ, Mósè pe Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì.

2. Ó sọ fún Árónì pé, “Mú akọ ọmọ màlúù kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò kan fún ẹbọ sísun, kí méjèèjì jẹ́ aláìlábùkù, kí o sì mú wọn wá sí iwájú Olúwa.

3. Kí o sì sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọmọ màlúù àti ọ̀dọ́ àgùntàn kan, kí méjèèjì jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun,

4. àti akọ màlúù kan àti àgbò kan fún ẹbọ àlàáfíà àti ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò láti fi rú ẹbọ ní iwájú Olúwa. Nítorí pé Olúwa yóò farahàn yín ní òní.’ ”

5. Wọ́n kó gbogbo àwọn nǹkan tí Mósè pa láṣẹ wá sí iwájú àgọ́ ìpàdé, gbogbo ìjọ ènìyàn sì súnmọ́ tòsí, wọ́n sì dúró níwájú Olúwa.

6. Nígbà náà ni Mósè wí pé, “Ohun tí Olúwa pa láṣẹ fún yín láti ṣe nìyìí, kí ògo Olúwa bá à lè farahàn yín.”

Ka pipe ipin Léfítíkù 9