Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 8:6-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà náà ni Mósè mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá ṣíwájú, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n.

7. Ó sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Árónì, ó fi àmùrè dì í, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìgúnwà, ó sì tún wọ̀ ọ́ ni aṣọ ìlékè oyè àlùfáà tí ó ní ìgbànú tí a ṣe ọnà dáradára sí.

8. Ó fi ìgbàyà sí àyà rẹ̀, ó sì fi Úrímù àti Júmímù síbi ìgbàyà náà.

9. Ó dé e ní fìlà, ó sì fi àwo wúrà tíí ṣe adé mímọ́ ṣíwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

10. Mósè sì fi òróró ìtasórí ya àgọ́ àti ohun gbogbo tó wà nínú rẹ̀ sí mímọ́.

11. Ó wọ́n díẹ̀ nínú òróró yìí sórí pẹpẹ lẹ́ẹ̀meje, ó ta òróró sórí pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò àti agbada pẹ̀lú ohun tó gbé agbada yìí dúró láti lè yà á sí mímọ́,

12. ó da díẹ̀ lára òróró ìtasórí yìí sórí Árónì, ó sì yà á sí mímọ́.

13. Lẹ́yìn èyí ló mú àwọn ọmọ Árónì wá ṣíwájú, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n, ó fi àmùrè dì wọ́n lára, ó fi fìlà dé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

14. Ó sì mú akọ mààlúù wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí ẹran náà.

15. Mósè pa akọ màlúù náà, ó sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí gbogbo ìwo pẹpẹ láti wẹ pẹpẹ náà mọ́. Ó da ìyóòkù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù fún un.

16. Mósè tún mú gbogbo ọ̀rá tó bo nǹkan inú, èyí tó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, ó sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ.

17. Ṣùgbọ́n akọ màlúù yìí pẹ̀lú àwọ àti ara ẹran àti ìgbẹ́ rẹ̀ ní ó sun lẹ́yìn ibùdó gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.

18. Lẹ́yìn náà ló mú àgbò wá fún ẹbọ sísun Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà.

19. Mósè sì pa àgbò náà, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.

20. Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ó sì sun orí àti àwọn ègé àti ọ̀rá rẹ̀.

Ka pipe ipin Léfítíkù 8