Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 8:30-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Mósè sì mú díẹ̀ lára òróró ìtasórí àti díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ láti orí pẹpẹ, ó wọ́n sára àwọn ọmọ Árónì àti aṣọ rẹ̀, ó sì tún wọ́n sára àwọn ọmọ Árónì àti aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Mósè ya Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ wọn sí mímọ́.

31. Mósè sì sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe ẹran náà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀ pẹ̀lú àkàrà tí a mú láti inú apẹ̀rẹ̀ ọrẹ ìfinijoyè àlùfáà gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé, ‘Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó jẹ ẹ́.’

32. Kí ẹ fi iná sun ìyóòkù àkàrà àti ẹran náà.

33. Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje, títí tí ọjọ́ ìfinijoyè àlùfáà yín yóò fi pé, nítorí pé ìfinijoyè àlùfáà yín yóò gba ọjọ́ méje gbáko.

34. Ohun tí a ṣe lónìí jẹ́ ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ láti ṣe ètùtù fún yín.

35. Ẹ gbọdọ̀ wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé lọ́sàn án àti lóru fún ọjọ́ méje kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa fẹ́, kí ẹ má ba à kú, nítorí ohun tí Olúwa pa láṣẹ fún mi ni èyí.”

36. Báyìí ni Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo tí Olúwa pa láṣẹ láti ẹnu Mósè.

Ka pipe ipin Léfítíkù 8