Ẹ má ṣe ṣè é pẹ̀lú yíìsìtì. Èmi ti fún àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nínú ẹbọ tí a fi iná sun sí mi! Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe jẹ́.