Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 4:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé,

2. “Ṣọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: bí ẹnìkan bá sèèsì ṣe ohun tí kò yẹ kó ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa.

3. “ ‘Bí àlùfáà tí a fi òróró yàn bá ṣẹ̀, tí ó sì mú ẹ̀bi wá sórí àwọn ènìyàn, ó gbọdọ̀ mú ọmọ akọ màlúù tí kò lábùkù wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Léfítíkù 4