Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 3:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú àgọ́ ìpàdé, kí àwọn ọmọ Árónì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.

9. Kí o sì mú wá nínú ẹbọ àlàáfíà náà, fún ẹbọ tí a fi iná se sí Olúwa; ọ̀rá rẹ̀ àti gbogbo ìrù rẹ̀ tí ó ní ọ̀rá, òun ni kí o mú kúrò súnmọ́ egungun ẹ̀yìn àti ọ̀rá tí ó bo ìfun lórí; àti gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ lára ìfun.

10. Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí o yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.

11. Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.

12. “ ‘Bí ó bá ṣe pé ewúrẹ́ ni ó mú, kí ó mú un wá ṣíwájú Olúwa.

13. Kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí. Kí ó sì pa á ní iwájú àgọ́ ìpàdé. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Árónì yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.

14. Lára ọrẹ tó mú wá, kí ó mú ọrẹ sísun fún Olúwa, gbogbo ọ̀rá tó bo nǹkan inú rẹ̀ àti ohun gbogbo tó so mọ́ ọn.

15. Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.

16. Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ tí a fi iná sun, ní òórùn dídùn. Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ jẹ́ ti Olúwa.

17. “ ‘Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ìran tó ń bọ̀, ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé: Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin Léfítíkù 3