Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 27:17-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Bí ó ba ṣe pé ní ọdún ìdásílẹ̀ ni ó yà ilẹ̀ náà sí mímọ́. Iye owó tí wọn sọ tẹ́lẹ̀ náà ni kí o san.

18. Bí ó bá ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ lẹ́yìn ọdún ìdásílẹ̀ kí àlùfáà sọ iye owó tí yóò san fún ọdún tó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ mìíràn tó pé iye owó tí ó gbọdọ̀ jẹ yóò dínkù.

19. Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà: kí ó san iye owó náà pẹ̀lú àfikún ìdá márùn-ún. Ilẹ̀ náà yóò sì di tirẹ̀.

20. Bí kò bá ra ilẹ̀ náà padà tàbí bí ó bá tàá fún ẹlòmíràn kò le è ri rà padà mọ́.

21. Bí a bá fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀ yóò di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí a fi fún Olúwa. Yóò sì di ohun ìní àlùfáà.

22. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ tí ó ti rà tí kì í ṣe ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa.

23. Kí àlùfáà sọ iye tí ó tọ títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ọkùnrin náà sì san iye owó náà ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ sí Olúwa.

24. Ní ọdún ìdásílẹ̀ ilẹ̀ náà yóò padà di ti ẹni tí ó ni ín, lọ́wọ́ ẹni tí a ti rà á.

25. Gbogbo iye owó wọ̀nyí gbọdọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ṣékélì ibi mímọ́ (ogún gera).

26. “ ‘Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ ya gbogbo àkọ́bí ẹran sí mímọ́. Èyí jẹ́ ti Olúwa nípaṣẹ̀ òfin àkọ́bí: yálà kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni tàbí àgùntàn, ti Olúwa ni.

27. Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹran tí kò mọ́, nígbà náà ni kí ó rà á padà gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, tàbí bí a kò bá rà á padà kí ẹ tà á gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀.

28. “ ‘Ohun tí a bá yà sí mímọ́ pátapáta láti ọwọ́ ẹnikẹ́ni sí Olúwa tàbí ẹranko tàbí ilẹ̀ tí ó jogún: òun kò gbọdọ̀ tàá kí ó rà á padà. Gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ bẹ́ẹ̀ di mímọ́ jùlọ fún Olúwa.

29. “ ‘Ẹni tí ẹ bá ti yà sọ́tọ̀ fún pípa, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ràá padà, pípa ni kí ẹ paá.

30. “ ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà yálà tí èso ilẹ̀ ni, tàbí tí èso igi, ti Olúwa ni. Mímọ́ ni fún Olúwa.

31. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá nǹkan rẹ̀ padà: o gbọdọ̀ fi márùn-ún kún un.

Ka pipe ipin Léfítíkù 27