Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 25:44-55 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

44. “ ‘Àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín lè jẹ́ láti orílẹ̀ èdè tí ó yí yín ká: Ẹ lè ra àwọn ẹrú wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn.

45. Bákan náà, ẹ sì le è ra àwọn àlejò tí ń gbé láàrin yín, àti àwọn ìdílé wọn tí a bí sáàrin yín. Wọn yóò sì di ohun ìní yín.

46. Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ bí ogún fún àwọn ọmọ yín; Wọ́n sìle sọ wọ́n di ẹrú títí láé. Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rorò mọ́ ọmọ Ísírẹ́lì kankan.

47. “ ‘Bí àlejò kan láàrin yín tàbí ẹni tí ń gbé àárin yín fún ìgbà díẹ̀ bá lọ́rọ̀ tí ọmọ Ísírẹ́lì sì talákà débi pé ó ta ara rẹ̀ lẹ́rú fún àlejò tàbí ìdílé àlejò náà.

48. Ó lẹ́tọ́ si ki a rà á padà lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ta ara rẹ̀. Ọ̀kan nínú ìbátan rẹ̀ le è rà á padà.

49. Àbúrò bàbá rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá a tan nínú ìdílé rẹ̀ le è rà á padà: Bí ó bá sì ti là (Lówólọ́wọ́) ó lè ra ara rẹ̀ padà.

50. Kí òun àti olówó rẹ̀ ka iye ọdún tí ó ta ara rẹ̀ títí dé ọdún ìdásílẹ̀ kí iye owó ìdásílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ iye tí wọ́n ń san lórí alágbàṣe fún iye ọdún náà.

51. Bí iye ọdún rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù bá pọ̀, kí iye owó fún ìràpadà rẹ̀ pọ̀.

52. Bí ọdún rẹ̀ kò bá pọ̀ sí àkókò ìdásílẹ̀, kí ó ṣe ìṣírò rẹ̀, kí ó sì san owó náà bí iye ìṣírò rẹ̀.

53. Bí ẹ ti ń ṣe sí i lọ́dọọdún, ẹ rí i dájú pé olówó rẹ̀ kò korò mọ́ ọ.

54. “ ‘Bí a kò bá rà á padà nínú gbogbo ọ̀nà wọ̀nyí, kí ẹ tú òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀.

55. Torí pé ìránṣẹ́ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ fún mi. Ìránṣẹ́ mi ni wọ́n, tí mo mú jáde láti Éjíbítì wá. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

Ka pipe ipin Léfítíkù 25