Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 25:3-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ọdún mẹ́fà ni kí ẹ fi gbin èso ọgbà yín, kí ẹ sì kórè èso wọn.

4. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje kí ilẹ̀ náà ní ìsinmi: ìsinmi fún Olúwa. Ẹ má ṣe gbin èso ọgbà yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ rò wọ́n.

5. Ẹ má ṣe kórè ohun tí ó tìkálárarẹ̀ hù: ẹ má ṣe kórè èso àjàrà ọgbà tí ẹ ò tọ́jú. Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ ní ìsinmi fún ọdún kan

6. Ohunkóhun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde ní ọdún ìsinmi ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún yín àní fún ẹ̀yin tìkálárayín, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín, àwọn alágbàṣe àti àwọn tí ń gbé pẹ̀lú yín fún ìgbàdíẹ̀.

7. Fún àwọn ohun ọ̀sìn yín, àti àwọn ẹranko búburú ní ilẹ̀ yín. Ohunkóhun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde ní ẹ lè jẹ.

8. “ ‘Ọdún ìsinmi méje èyí tí í ṣe ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta ni kí ẹ kà.

9. Lẹ́yìn náà, kí ẹ fọn fèrè ní gbogbo ibikíbi ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kéje ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́. Ní ọjọ́ ètùtù yìí, ẹ fọn fèrè yíká gbogbo ilẹ̀ yín.

10. Ẹ ya àádọ́ta ọdún náà sọ́tọ̀ kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo ẹni tí ń gbé ilẹ̀ náà. Yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Kí olúkúlùkù padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀.

11. Àádọ́ta ọdún ni yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Ẹ má ṣe gbin ohunkóhun, ẹ kò sì gbọdọ̀ kórè ohun tí ó hù fúnrarẹ̀ tàbí kí ẹ kórè ọgbà àjàrà tí ẹ kò dá.

12. Torí pé ọdún ìdásílẹ̀ ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún yín. Ẹ jẹ ohun tí ẹ mú jáde nínú oko náà.

Ka pipe ipin Léfítíkù 25