Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 25:26-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ẹni tí kò ní ẹni tó lè ràápadà fún un, tí òun fúnrarẹ̀ sì ti lọ́rọ̀, tí ó sì ní ànító láti rà á.

27. Kí ó mọ iye owó tí ó jẹ fún iye ọdún tí ó tà á, kí ó dá iye tí ó kù padà fún ẹni tí ó tà á fún: lẹ́yìn náà, ó lè padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

28. Ṣùgbọ́n bí kò bá rí ọ̀nà àti san án padà fún un. Ohun tí ó tà wà ní ìkáwọ́ ẹni tí ó ràá títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ó dáa padà fún ẹni tí ó ni i ní ọdún ìdásílẹ̀, ẹni tí ó ni í tẹ́lẹ̀ lè tún padà gbà ohun ìní rẹ̀.

29. “ ‘Bí arákùnrin kan bá ta ilẹ̀ tí ó wà nínú ìlú, ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á padà láàrin ọdún kan sí àkókò tí ó tà á.

30. Ṣùgbọ́n bí kò bá rà á padà láàrin ọdún náà ilé náà tí ó wà láàrin ìlú ni kí ó yọ̀ǹda pátapáta fún ẹni tí ó rà á, àti àwọn ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n má da padà ní ọdún ìdásílẹ̀.

31. Ṣùgbọ́n àwọn ilé tí ó wà ní abúlé láìní odi ni kí a kà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ oko, a lè rà wọ́n padà, kí wọ́n sì da padà ní ọdún ìdásílẹ̀.

32. “ ‘Àwọn ọmọ Léfì ní ẹ̀tọ́, nígbàkugbà láti ra ilẹ̀ wọn, tí ó jẹ́ ohun ìní wọn ní àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Léfì.

33. Torí náà ohun ìní àwọn ọmọ Léfì ni wọ́n rà padà, fún àpẹẹrẹ, èyí ni pé ilẹ̀ tí a bá tà ní ìlúkílú tí ó jẹ́ tiwọn, ó sì gbọdọ̀ di dídápadà ní ọdún ìdásílẹ̀, torí pé àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní ìlú àwọn Léfì ni ìní wọn láàrin àwọn ará Ísírẹ́lì

34. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí wọ́n ti ń da ẹran tí ó jẹ́ ti ìlú wọn, wọn kò gbọdọ̀ tà wọ́n, ilẹ̀ ìní wọn láéláé ni.

35. “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá talákà tí kò sì le è pèsè fún àìní ara rẹ̀: ẹ pèsè fún un bí ẹ ti ń ṣe fún àwọn àlejò tàbí àwọn tí ẹ gbà sílé: kí ó baà leè máa gbé láàrin yín.

36. Ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé kankan lọ́wọ́ rẹ̀: ẹ bẹ̀rù Olúwa kí arákùnrin yín leè máa gbé láàrin yín.

37. Ẹ má ṣe gba èlé lórí owó tí ẹ yá a bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ èrè lórí oúnjẹ tí ẹ tà fún un.

38. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì láti fún yín ní ilẹ̀ Kénánì àti láti jẹ́ Ọlọ́run yín.

Ka pipe ipin Léfítíkù 25