Lẹ́yìn aṣọ títa tibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Árónì ti tan iná náà níwájú Olúwa, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀.