21. Ní ọjọ́ yìí náà ni kí ẹ kéde ìpàdé àjọ mímọ́: ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́ Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀ níbi yòówù tí ẹ ń gbé.
22. “ ‘Nígbà tí ẹ bá kórè ilẹ̀ yín ẹ má ṣe kórè dé ìkangun oko yín, tàbí kí ẹ padà gé èyí tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ nínú ìkórè yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn tálákà àti àwọn àlejò: Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”
23. Olúwa sọ fún Mósè pé
24. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì: ‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, kí ẹ ní ọjọ́ ìsinmi, ìpàdé àjọ mímọ́ tí a fi fèrè fífọn ṣe ìrántí
25. Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojúmọ́, ṣùgbọ́n ẹ mú ọrẹ tí a fi iná sun wá ṣíwájú Olúwa.’ ”
26. Olúwa sọ fún Mósè pé,
27. “Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ni ìpàdé àjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣẹ́ ara yín kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa.
28. Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, torí pé ọjọ́ ètùtù ni, nínú èyí tí a ń ṣe ètùtù fún yín níwájú Olúwa Ọlọ́run yín.
29. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣẹ́ ara rẹ̀ ní ọjọ́ náà ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
30. Èmi yóò pa ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́kiṣẹ́ ní ọjọ́ náà run kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
31. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.
32. Ọjọ́ ìsinmi ni fún yín, ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà, títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, ni kí ẹ fi sinmi.”
33. Olúwa sọ fún Mósè pé,
34. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù keje ni kí àjọ̀dún ọdún Àgọ́ ti Olúwa bẹ̀rẹ̀ kí ó sì wà títí di ọjọ́ méje.
35. Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìpàdé mímọ́: ṣẹ kò gbọdọ̀ e iṣẹ́ ojúmọ́.
36. Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá, ní ọjọ́ kẹjọ ẹ pe ìpàdé mímọ́ kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa, èyí jẹ́ ìpàdé tí ó gbẹ̀yìn; ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojojúmọ́.